gbé Ajé (Live)-文本歌词

gbé Ajé (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ọ̀rẹ́ ìyàndá ọjọrá gbogbo Ajé ẹ kú ìkàlẹ̀ Àyìndé Olúayé Fújì Mo ri yín lọ́dún yìí 2025 ẹ ẹ̀ ní bá wọn káwọ́ ẹkún lérí Ẹ ẹ̀ dẹ̀ ní ṣòwò àṣedànù òwò àṣẹ lówó lọ́wọ́ èyí tí ẹ tí ń ṣe Kudi dáadáa tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́hun tún bá mi fun yín Ọlá ọwọ́ọ yín ò wá ní kan Ìsàlẹ̀ àpò Ẹ ẹ̀ ní jáde lé ikú lọ́wọ́ Ajé! Bó w’ọlá Ọlọ́hun ẹ ṣe àmín àṣẹ Eluku (Bó w’ọlá Ọlọ́hun ẹ ṣe àmín àṣẹ) Lukman ńkọ́ bàbá ọmọ méjì mi ọmọ ìdòwú Eluku ìdòwú Olórí ẹgbẹ́ ajé Ọlá Ajé ń báwa sùn Ajé ń báwa jí Ajé ò ní fiwá sílẹ̀ ńṣe la jọ máa gbé (Ajé ń báwa sùn Ajé ń báwa jí) (Ajé ò ní fiwá sílẹ̀ ńṣe la jọ máa gbé) Gbogbo ọ̀nà lomi ń bá wọnú ajere ọlá Ajé ń báwa sùn Ajé ń báwa jí Ajé ò ní fiwá sílẹ̀ ńṣe la jọ máa gbé (Ajé ń báwa sùn Ajé ń báwa jí) (Ajé ò ní fiwá sílẹ̀ ńṣe la jọ máa gbé) Mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé (gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Ìyàndá, mo kí ẹ kí ẹ o (mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Ọjọrá Kasime (mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Èèyàn t’ọlá Massive (mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Mr screen Ìdòwú ìrọ̀rùnọlá bàbá ọmọ méjì mo kí ẹ kí ẹ (Mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Ọmọ Lawali Murphy (mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Ọmọ t’Ògúnmádé Fatai (mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Najim Eluku ọmọ bàbá mi happy New Year to you O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn (mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Akeem ọmọ Ọlábọ̀dé o kú ọdún mo kí ẹ o (Mo kí gbogbo ẹgbẹ́ ajé) Sulemona olówó olówó ni Sule (Sule maito) Seékẹ́ olówó ni Sule (olówó Sule maito) Ori Orí Arsenal Èní la ṣílé ẹ̀gbẹ́ wa o (Sule maito) Orí èní la ṣílé ẹgbẹ́ wa o (Sule maito) Olówó ni Sule (olówó Sule maito) Muniru lawanson (ọmọ ẹgbẹ́ ajé) Muniru lawanson (ọmọ ẹgbẹ́ ajé) Lásúnkànmí (olásúnkànmí) Sunky ni Lásúnkànmí (olásúnkànmí) Olásúnkànmí (olásúnkànmí) Àwẹ̀dá Kamaru (Olásúnkànmí) Àwẹ̀dá Kamaru (awo olásúnkànmí) Èèyàn ti Jídé o (Ọmọ òyékàn) Èèyàn ti Jídé o (Ọmọ òyékàn) Ọlá ọmọ Williams gbogbo yín pátápátá mo ri yín lọ́dún yìí Inú owó lẹ máa wà amina Olórí gbogbo ẹgbẹ́ ajé President Ajé club highlander mo kí ẹ Highlander mo kí ẹ Gbogbo yín àdúà á máa gbà arábámbí Ọdún yìí á tù wá lára o, á tùwá lára o (Àsìkò yìí o, ìgbà yìí o á tù wá lára o) Ẹgbẹ́ ajé 2025, Àní á tù wá lára o á tùwá lára o (ìgbà yìí o, àsìkò yìí o yí ó tù wá lára o) Ọmọ ẹgbẹ́ ajé (Ọmọ ẹgbẹ́ ajé) Èèyàn ti Ìyàndá Kazeem Ọláolúwa kìí tán (Ọlá Olúwa kìí tán) Ìyàndá wọ́n jíṣẹ́ ẹ fún mi (ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Èèyàn t’ori Arsenal (ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Ọlá máa bá n tọ́jú Sunky (ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Èèyàn t’Eluku Najimu (ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Àwọn èrò tó re Canada wọ́n ní kí n kí ẹ (Ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Gbogbo wọn ni wọ́n ní n kí ẹ (Ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Àpòo yín ò ní lu (ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Gbogbo dada tẹ ti gbé ilé ayé ṣe (ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Èyí tẹ́ ẹ ti gbé’lé ayé ṣe o (Ọlá Olúwa kìí tán, ọlá Olúwa kìí tán) Àyìnlá adé À ń jó’jó ọdún 2025 Ṣótirẹ̀ má mikàn Àdéhùn Ọlọ́hun Ọba Àyìndé kò ní yẹ̀ lórí everybody o Ọdún owó la wà Ẹni t’órí bá ti dá o orí ti dá ìyẹn ná #INSTRUMENTAL Ẹni t’órí bá ti dá o orí ti dá ìyẹn ná Kí wọ́n yé lépa kádàrá Bí èèyàn kan lépa kádàrá lásán aṣọ ẹ̀ á fàya Àní ẹni t’órí bá ti dá o o orí ti dá ìyẹn ná Ẹ má lépa kadara Bí èèyàn kan lépa kádàrá lásán aṣọ ẹ̀ á fàya ni Nípa ọ̀rọ̀ ilé ayé àwọn solo mákindé Kí ló ń jẹ́ Solo mákindé? Ah òfófó ò gb’ẹgbàá o ibi ọpẹ́ ló mọ Ló ń jẹ́ solo mákindé Abẹnúgun lẹ̀bá’tí sọló mákindé Àní ẹni t’órí bá ti dá o orí ti dá ìyẹn ná Àní ẹni t’órí bá ti dá o orí ti dá ìyẹn ná Kí wọ́n yé lépa kádàrá bí èèyàn kan lépa kádàrá lásán aṣọ ẹ̀ á fàya ni Sọló Mákindé èké ilé A wáa yín délé, a ò ba yín nílé Ọmọ yín la bá tó ń jẹ́ ojúyọbọ òfófó lojú wà Àwọn eyes kongbà Bí ẹ bá rí wọn lọ́nà ẹ wò’wọ́n re Ẹni tí a ò fi’ṣẹ́ rán Èké ilé ló ń jẹ́ Sọló Mákindé Níbi wọ́n ń gbé rojọ́ ká fìla wọn bá ṣí L’afẹ́fẹ́ gbé’yẹn lọ Ibi wọ́n gbé rojọ́ ká èyí obìnrin nínúu wọn Ìyẹn t9 ń jẹ́ Deborah láṣọ ẹ̀ bá kọ́ igi l’aṣọ bá fàya Ah Sọló Mákindé a wá a yín délé A ò bá yín nílé ọmọ yín la bá tó ń jẹ́ ojúyọbọ Òfófó lójú wà àwọn eyes kongbà o Bí wọ́n bá pè mí lágbo fújì ma ya lọ (Ma jó ma yọ̀) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ (Má jó ma yọ̀) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ (Má jó ma yọ̀) Bí wọ́n bá pèmí lágbo Fújì ma ya lọ (Má jó ma yọ̀) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ (Má jó ma yọ̀) Ma jó ma yọ̀ o (óyá ma jó ma yọ̀ o) Ma jó ma yọ̀ o (óyá ma jó ma yọ̀ o) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ (Má jó ma yọ̀) Má ranjú mọ́ mi mọ́ (Sọló Mákindé) Má ranjú mọ́ mi mọ́ o (Sọló Mákindé) Ìwọ nìkan kọ́ lo lójú (Sọló Mákindé) Èké ilé (Sọló Mákindé) A wáa yín délé (Sọló Mákindé) A ò ba yín nílé (Sọló Mákindé) Ọmọ yín la bá (Sọló Mákindé) Ló ń j’ójúyọbọ́ (Sọló Mákindé) Òfófó lojú wà Àyìndé (Sọló Mákindé) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀ ) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ