(Ma jó ma yọ̀) Bí wọ́n pèmí lágbo Fújì ma ya lọ Bí wọ́n pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀) Bí wọ́n pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀) Bí wọ́n pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀) Bí wọ́n bá pè mí lágbo Fújì ma ya lọ (ma jó ma yọ̀) Ìràwọ̀ òní mushin àjíná Mo throw respect Àyìndé Wasiu arábámbí Ọba orin Al - Akeem Bernado Bernado Gbogbo yín ẹ kú ọdún Oodua dà? Gbogbo yín tí ẹ wá láti London àbí America àbí Canada Ẹ káàbọ̀ sí Nigeria mo kí i yín o Èjìrẹ́ ọmọ Ọba Ọmọ ọmọ olówó èkó Àrà ni gbogbo nǹkan nílée yín Ìrókò nílàdó ọmọ ọ̀sànyìn’làwẹ̀ Èpò wẹ́rẹ́ lójúde t’ìlàdó Kò ṣeé fọkọ́ ro kò ṣeé f’àdá ro ó O ò kẹ̀dẹ̀ ró o ò kúrò níbẹ̀ Ọmọ ilá tí ò ti ibì kan wá Ọmọ ọ̀nà ò ti ibìkan wọ ọjà Òtòṣí ṣubú lọ́jà wọ́n b’ẹ̀rín rín Bí olórí ilé bá ṣubú Ọmọ́gbọ́láhàn ẹ wo ẹkún lala Mo kíi yín ẹ kú ọdún Àmọ̀kẹ́ màmá Sójà Bọ́láńlé Aya bàbá Sójà ẹ ẹ̀ ri iṣan ọrùn ẹ ni Èèyàn Olúwafẹ́mi ṣótirẹ̀ Àyìnlá adé ọmọ Agara Ọlọ́hun ò jẹ́ Ìyá aláṣọ wa Gbogbo yín ni mo kí ẹ kú ọdún Pastor dà? Àdúà tí ẹ fi jagun fún wa o Ẹ ṣọ́ fún wa lọ́rọ̀ Ẹ ní kí gbogbo wa ká lọ fún fún àdúà Ẹ ní ká gbàá l’áàwẹ̀ wí pé ogun máa pọ̀ 2024 Ẹ ní ìjì máa jà ihun tó jẹ́ kí èmí gbà, etí inú Èèyàn Tó bá ń rorí Lára ohun tí ò gbọdọ̀ fi máa ṣeré Ohun ni àdúà, agbára ò lè ṣé àdúà ló ń jẹ́ ìbẹlọ́hun Ọba o Yí ó ṣe é fún gbogbo wa Gbogbo àwọn tó ń fi àdúrà jagun Ibi ọ̀tọ̀tọ̀ ọ̀rọ̀ kan ni wọ́n ń sọ o Ọ̀rọ̀ kan ṣo ni wọ́n ń sọ Wọ́n ní 2024 Dangote wọ́n ní ìjì máa jà Wọ́n ní afẹ́fẹ́ máa fẹ́ wọ́n ní gbogbo ewéko á máa ṣe lágbálúgbú Wọ́n ní omi á máa rú Àyìndé ọmọ Ayọ̀ọlá Wọ́n ní bó tilẹ̀ wù tó bó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ o Àgbọn orí ẹ̀, wọ́n ní kò ní jábọ́ Adamson, wọ́n ní ká ṣe mẹ̀dọ̀ ká f’ọwọ́ wọ́nú Pé ohun tí ò tó ń bọ̀ wá ṣẹ́kù ọmọ osú Wọ́n ní tí a bá fi la òkun náà já Láti 2024 t’a fi wọ 25 wọ́n ní à á dúpẹ́ fún Elédùmarè à á sọpẹ́ fún Ọlọ́hun Pastor Fáṣawẹ̀ ẹ má dákẹ́ Àdúà ló lè ṣé kì í ṣe agbára Mo dúpẹ́ dúpẹ́ ẹ kú àdúrótì Èṣìléwù èṣù pàtẹ ọjà ó ku bàbá ẹni tí ó ba na Èèyàn t’Àyìnlá mi too much mi Àyìnlá ọmọ Agara too much money kẹ́ ẹ bá mi ki Ìwọ ni mo fi iṣẹ́ yẹn rán Ọmọ osú Àyìnlá ọmọ Agara too much money kẹ́ ẹ bá mi ki Adamson ṣé ọ̀rẹ́ ẹ ti dé láti Saudi Ara àwọn tó ń fi àdúrà jagun nìyẹn o Ó dé Saudi ó pè mí ó ní Alhaji ẹ fọkàn balẹ̀ àdúà ló lè ṣé Eh eh KC bó o ṣe má ń sẹ̀mí lọ́wọ́ 2025 o tún dé bó o ṣe ń dé Jí’ọ́n mọ̀ Àìmọye ni ò mọ ìtumọ̀ jí’ọ̀n mọ̀ Jí’ọ́n mọ̀ níṣe ló dàbí ọmọ àti ìkejì ọmọ Tó bá possible ìsẹ̀yín ni wọ́n ń bímọ tí wọ́n ń ju ibi ọmọ nù Àwọn tí wọ́n bí wa láyé àtijọ́ Àyìndé wọn kì í sọ ibi ọmọ nù Ibi tí wọ́n bá gbe sí Ọmọ́gbọ́láhàn wọ́n á f’àmì si ni Tó bá tújú bí ọmọ bá ń s’àárẹ̀ Tí wọ́n bá so gbogbo nǹkan fun Ibi ibi ọmọ ni wọ́n máa lọ Wọ́n á tùú wọ́n á bàá ara ọmọ á balẹ̀ á pé Òhun ni ibi mi ọmọ mi o Tàn-án mú àti Ajígbẹ́dà ọ̀rẹ́ mi Àyìndé Wasiu mi pẹ̀lú Jí’ọ́n mọ̀ ọmọ Bísọ́lá Jí’ọ́n mọ̀ Gbogbo yín k’órí bá mi dáa yín sí Ikú òní pa yín fún mi Àmọ̀kẹ́ mama Sójà mo kí ẹ Bọ́láńlé Ọ̀rọ̀ lágbájá tó gbọ́ kùkù òjò Ó bọ sẹ́yìnkùlé o d’omi inú agbada nù o Christy ọ̀rọ̀ lágbájá tó gbọ́ kùkù òjò tó bọ́ sẹ́yìnkùlé o Ó d’omi agbada nù o Ìgbà tó yá ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ kò tún padà rọ̀ o Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní y’òòrùn Akin ọmọ Arógundádé Eluku Gbogbo yín ni mo kí ọdún 2025 á san oore fún gbogbo wa A ò ní ṣòwò àìpé Bí a bá rán owó níṣẹ́ ńlá ni ó padà wá báwa nílé Ọmọ Adétòrò Àyìndé dà? Ayédáadé Oníkiní púpọ̀ tó fi bí igba ọmọ Ayédáadé alábínú a máa sá sí Àyìndé mi Musiliu Ayédáadé Ìjí jà afẹ́fẹ́ fẹ́ àgbọn ò jábọ́ débi omi àgbọn máa dànù Adúpẹ́ fún Elédùmarè a dúpẹ́ f’Ọ́lọ́hun Ọba Sọ fún Modina pé kó má dákẹ́ àdúà ìyá ọmọ méjì ẹdúnjọbí Iṣu ọmọ á jóná fún ẹ jẹ Kó o jíṣẹ́ mi fún Tọ́pẹ́ àti ọmọ Ojúṣàágbọlá mi Ọ̀gọ́jì Toppy T Ìbàdàn, gbogbo yín ni mo kí kú ọdún Kí ẹ bá mi kí ọmọ Ojúṣàágbọlá Aishatu kẹ́ ẹ bá mi ki Oríyọmí Aminatu àbúrò Àṣàkẹ́ Ìdáyátù ọmọbọ́lájí Àwọn ọmọ Adégoróyè mi ẹ̀gbọ́n Yọ̀mádé mi Sule olówó Ẹ̀gbọ́n ti Al-amin ọmọ mi tọ̀míwá Ẹ̀gbọ́n Fatimo, Ẹ̀gbọ́n Dámilọ́lá Ó ṣe jẹ́ ìwọ ẹ̀gbọ́n ẹ̀gbọ́n wọn ò tiẹ̀ pè ẹ́ ní àbúrò èèyàn kankan, kílódé? Ìwọ ẹ̀gbọ́n fún everybody Ọmọ́bọ́lájí Àṣàkẹ́ o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn àbúrò àbẹ̀ní Monsuratu Ajíbádé Àbúrò Àlàdé mi Azeez tó jẹ́ olórí ẹbí O mà lucky gan àwọn méjì níwájú ìwọ nìkan Ó wá lérò lẹ́yìn Ah! Ẹ̀gbọ́n t’Àńjọláolúwa Àbíkẹ́ Ìgbà tó yá Ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ Àyìndé Ó tún padà wọ̀ Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní y’òòrùn o Ayọ̀bámi ọmọ Awóyẹmí Ayọ̀ Radical ayọ̀ classical Omọ Àmùdá Yusufu mi Tayọ o ṣe ọdún eléyìí wà á ṣe ẹ̀míì tọmọ tọmọ Ah obìnrin bí ọkùnrin ọmọ Surajudeen mi ọmọ Kẹ́shinró Nílùú Ìjẹ̀bú Òde Dérónkẹ́ Aisha, ẹ̀wà àgọ̀nyìn dà? Ẹ̀wà àgọ̀nyìn dà? Ẹ̀wà àgọ̀nyìn tí wọ́n fi Sugar sí Stand to be recognised Ẹ sọ fun rántí pé ẹnìkan ń bẹ tó ń retí oore Ọlọ́hun Ọba Ìwọ nìkan kọ́ La dá ilé ayé fún Àìmọye ló ń bẹ o tó ń retí oore Ọlọ́hun Ọba Ìdùnnú wa lo jẹ́ O ò ní dọlárẹ̀yìn lọ́lá Elédùmarè lọ́lá Ọlọ́hun Ọba Gbogbo yín ni mo dúpẹ́ fún ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ẹ kú ọdún Mo mọ̀ ọ́ lóore Ká ríra wa bá Ṣọ́balójú ó wá láti America mo kí ẹ ṣọ́balójú Ah! Torí kíni ó ṣe dáadáa? Adiso Àyìndé kíni ó ṣe dáadáa? Ó ń dúpẹ́ Kín ni ó ṣe dáadáa? Jaguar, kí ni ó ṣe dáadáa Kín ni ó ṣe o (dáadáa) Àní kí ni ó ṣe (dáadáa) Ma ṣe dáadáa láyé mi (dáadáa) Èmi ò mà ní ṣèkà o Ayédáadé kí lo ó ṣe? (dáadáa) Àní kí lo ó ṣe (dáadáa) Ọlámilékan kí lo ó ṣe? (dáadáa) Yíbíọ̀nà kí lo ó ṣe? (dáadáa) Àní kí lo ó ṣe? (dáadáa) Ah kí ló ó ṣe? (dáadáa) Abby kí lo ó ṣe? (dáadáa) Ìwọ ò mà níí ṣe ìkà o (dáadáa) Ẹ jẹ́ ká máa ṣé (dáadáa) Mo ní kí lo ó ṣe (dáadáa) Kí lo ó ṣe (dáadáa) Kí lo ó ṣe (dáadáa) Kí lo ó ṣe (dáadáa) Àní kí lo ó ṣe (dáadáa)